Akọle :: Darijimi ololufẹmi
Akewi::Bamgbọpa
Adeṣẹwa
Ologuna kan
Kii ṣere l'eti odo ni wọn wi
Oun lo je n ra'wọ ẹbẹ si ẹ ololufẹ mi
Dakun dabọ Ki o fiye denu
Aṣiṣe ni oun ti o ṣẹlẹ
Adeṣẹwa
A ki i rin lọ
K'ori ma mi l'ara ẹda
Bẹẹ a rẹ ma'ja kan o si
Lootọ ọbẹ ti ge ọmọ lọwọ
Ka s'ọbẹ nu
Ohun kọ ni ọna abayọ
Dakun foriji mi ololufẹ mi
Adeṣẹwa
Ati igba ti o ti pinya pẹlu mi
Oun ara mi o ti balẹ mọ
Ti ẹmi mi si n ṣe waruwaru
Aye wa di ọrun apadi lara mi
Adeṣẹwa
Bi a ba j'ẹkọ
A dari j'ewe la gbọ
Kiwa lode ti o f'aake kọri
Toni o ni gbẹbẹ
Dakun dabọ fiye denu
Ki o f'ori ji mi
Adeṣẹwa
Bi a ba f'ọwọ ọtun b'ọmọ wi
A fi t'osi fa mọ'ra
Bẹẹni ki o ṣe mi ololufẹ mi
Mo si ṣe ileri pe
Iru rẹ ko tu ni ṣ'ọmọ lọwọ mi ololufẹ mi
©bamgbopa55
B